Ohun tó wà nínú ojú-ìwé yìí
- Ìdí tí ẹni tó mọ Yorùbá dáadáa fi ń pàdánù àmì
- Ìlànà note-taking fún NAATI CCL
- Àpẹẹrẹ note-taking fún segment kan
- Àwọn ibi mẹ́fà tí ó yẹ kí ẹ ṣọ́ra fún láàrín Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì
- Ohun tí ẹ ó ṣe bí ọ̀rọ̀ bá bọ́ lọ́wọ́ yín
- Ètò ìdánrawò ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí mẹ́fà
- Bí a ṣe ń lo àwọn fídíò ìdánrawò ọ̀fẹ́ lórí YouTube
- Ìgbáradì ọjọ́ ìdánwò (yàrá àti ẹ̀rọ)
- Àwọn ìbéèrè tó wọ́pọ̀
Ìdí tí ẹni tó mọ Yorùbá dáadáa fi ń pàdánù àmì
Ìgbọ́ràn kì í ṣe ibi tí àmì ti ń sọnù. Ẹni tí ó ń ṣe ìdánwò yìí ní Yorùbá sábà máa ń jẹ́ ẹni tí ó lè bá ìyá rẹ̀ sọ̀rọ̀ ní Yorùbá fún wákàtí kan láìsí wàhálà, tí ó sì ń ka ìwé Gẹ̀ẹ́sì ní ibi iṣẹ́ ní Sydney tàbí Melbourne ní gbogbo ọjọ́. Ẹnu ni ó ń wó, lábẹ́ aago.
Ìyàtọ̀ wà láàrín sísọ Yorùbá àti gbígbé ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn ní Yorùbá. Nígbà tí ẹ bá ń bá ẹbí yín sọ̀rọ̀, ẹ̀yin ni ẹ ń yan ọ̀rọ̀ náà: ohun tí kò bá wá lọ́wọ́ yín, ẹ ó yí i ká. Nínú ìdánwò náà, ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn ni ẹ ń gbé, ọ̀nà ìyíká kò sì sí. Bí ‘bond’, ‘referral’ tàbí ‘rollover’ bá dé, ó dé.
Ìyẹn ni ìdí tí ẹni tí Yorùbá rẹ̀ dára jù fi máa ń gbáradì díẹ̀ jù. Ó gbọ́ dialogue ọ̀fẹ́ kan ti NAATI, ó yé e ní pátápátá, ó sì kà á sí pé ó ti mọ̀ ọ́n. Ohun tí kò ṣe ni pé kí ó gba ohùn ara rẹ̀ sílẹ̀ kí ó sì tẹ́tí sí i. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó máa ń wà nínú ìgbàsílẹ̀ ohùn àkọ́kọ́ ẹnì kan:
- Ìdádúró gígùn nígbà tí ẹ bá ń wá ọ̀rọ̀ Yorùbá fún ‘bulk billing’ tàbí ‘urgent repair’
- Ìdájọ́ kẹta tí ó bọ́ sílẹ̀ pátápátá nítorí pé ẹ ṣì ń ronú lórí ìdájọ́ àkọ́kọ́
- Nọ́mbà tí ó yí padà: ọ̀sẹ̀ méjì di oṣù méjì, ọjọ́ kẹrìnlá di ọjọ́ kẹrin
- Àfikún tí ẹ kò mọ̀ pé ẹ fi kún un: ‘ó ṣeé ṣe kí’, ‘bóyá’, ‘mo rò pé’ tí kò sí lẹ́nu olùsọ̀rọ̀ rárá
Ìmọ̀ ni gbogbo rẹ̀, kì í ṣe ẹ̀bùn àbínibí. Ẹnu ni a fi ń kọ́ ọ.
Ìlànà note-taking fún NAATI CCL
Àkọsílẹ̀ (note) inú NAATI CCL ní iṣẹ́ kan ṣoṣo: kí ó dá ohun tí ó ti bẹ̀rẹ̀ sí í rẹ̀wẹ̀sì nínú ìrántí yín padà. Ẹ kò ní àkókò láti kọ gbólóhùn kíkún, ẹ kò sì gbọ́dọ̀ gbìyànjú rẹ̀. Ohun mẹ́ta ni ó sábà ń sọnù kúrò nínú ìrántí nígbà tí segment kan bá gùn: díjítì, àìsí, àti ohun kẹta nínú àtòjọ.
- Nọ́mbà àti ìwọ̀n. Ẹ kọ díjítì (14, 3:30, 2,240) pẹ̀lú ohun tí ó jẹ́ ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀: ọjọ́, dọ́là, ìgbà mélòó, ọdún mélòó. Díjítì kan tí ó bọ́ jẹ́ àmì tí ó lọ, kò sì sí ọ̀nà láti mú un padà.
- Ọ̀rọ̀ àìsí. ‘Kò sí’, ‘ẹ má ṣe’, ‘wọn kò tíì’. Ẹ mú àmì kan tí ẹ ó mọ̀ (ìlà tí a fà kọjá ọ̀rọ̀ kan, tàbí àmì ‘¬’). ‘Wọn kò tíì gba ìwé yín’ tí ó jáde lẹ́nu yín bí ‘wọ́n ti gba ìwé yín’ ti yí gbogbo ìpè náà padà.
- Àtòjọ. Ohunkóhun tí ó ju ohun méjì lọ: ìwé mẹ́ta, ìdí mẹ́ta, ààyè mẹ́ta. Ẹ kọ wọ́n ní ìtẹ̀lé, ọ̀kọ̀ọ̀kan lórí ìlà tirẹ̀. Ohun kẹta ni ó sábà máa ń sọnù.
- Orúkọ. Orúkọ ènìyàn, ìlú, àjọ àti fọ́ọ̀mù ni kí ẹ kọ ní Gẹ̀ẹ́sì gan-an bí ó ṣe dé: Centrelink, Medicare, Werribee, Form 1. A kì í túmọ̀ wọn, a kì í sì í ké wọn kúrú.
- Ìsopọ̀ ọgbọ́n. ‘Nítorí’, ‘ṣùgbọ́n’, ‘bí… bá’. Ọfà kan (→) ń gba ìdí àti àbájáde là; ìlà tí ó dúró ṣánṣán ń pín ohun tí ó ṣẹlẹ̀ kúrò lára ohun tí yóò ṣẹlẹ̀.
Èdè tí ọwọ́ yín yára jù ni kí ẹ fi kọ ọ́. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n kàwé ní Nàìjíríà yára ní Gẹ̀ẹ́sì, nítorí Gẹ̀ẹ́sì ni wọ́n ti fi ń kọ̀wé láti ilé-ẹ̀kọ́ alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀. Kò sí ẹni tí ń wo àkọsílẹ̀ yín, kò sì sí àmì fún un. Ẹ lè fi àmì ohùn àti àmì abẹ́ sílẹ̀ pátápátá níbẹ̀, ẹ lè fi Gẹ̀ẹ́sì kọ ìdajì kan kí ẹ sì fi Yorùbá kọ ìdajì kejì. Ohun kan ṣoṣo tí ó ṣe pàtàkì ni pé kí ẹ lè kà á padà ní ojú ẹsẹ̀.
Ẹ ké ọ̀rọ̀ kúrú, kí ẹ sì lo àmì kan náà ní gbogbo ìgbà: Ctr fún Centrelink, Dr fún dókítà, k fún ẹgbẹ̀rún, ‘w/’ fún pẹ̀lú. Ìkékúrú tí ẹ ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣẹ̀dá ní ọjọ́ ìdánwò kì í ṣiṣẹ́; èyí tí ẹ ti kọ ní ọgọ́rùn-ún ìgbà ni ó ń ṣiṣẹ́.
Àpẹẹrẹ note-taking fún segment kan
Segment tí ó tẹ̀lé yìí jọ ohun tí ó lè dé nínú dialogue ilé. Ìjà wà láàrín ẹni tí ń yá ilé àti ilé-iṣẹ́ abániwálé, òṣìṣẹ́ ilé-iṣẹ́ náà sì ń sọ̀rọ̀ ní Gẹ̀ẹ́sì.
Ohun tí ẹ gbọ́: “The owner has agreed to fix the leaking roof, but not before the fourteenth. Your bond is 2,240 dollars and it is held by the RTBA, not by our agency. If you want the repairs sooner than that, you can lodge an urgent repair request with the tribunal.”
Àkọsílẹ̀ (note) tí ó tó:
- owner OK → orùlé (leak)
- ¬ ṣáájú 14th
- bond 2,240 → RTBA (¬ agency)
- yá ju bẹ́ẹ̀? → urgent repair req → tribunal
Ìlà mẹ́rin, ọ̀rọ̀ díẹ̀. Ṣùgbọ́n ohun mẹ́rin tí ó lè pa àmì ni wọ́n gbé: àìsí méjì (kò ní ṣẹlẹ̀ ṣáájú ọjọ́ kẹrìnlá; kì í ṣe ilé-iṣẹ́ náà ni ó gbé owó náà), díjítì méjì, orúkọ àjọ kan tí a kò gbọ́dọ̀ túmọ̀, àti ipò kan tí ó gbọ́dọ̀ dúró bí ipò (bí ẹ bá fẹ́ kí ó yá). Àwọn àìsí méjì náà ni ó rọrùn jù láti fò, ìyẹn sì ni ó ń yí ìtumọ̀ gbogbo segment náà padà.
Ní ẹ̀gbẹ́ kejì, ẹni tí ń yá ilé náà dáhùn ní Yorùbá: “Òjò ti bà á jẹ́ lẹ́ẹ̀mejì lóṣù yìí. Wọ́n ní kí n dúró, ṣùgbọ́n ọmọ mi obìnrin ní ààrùn ikọ́ èémí, ilé náà sì ti kún fún ìmùkúmùkú.” Àkọsílẹ̀ náà lè jẹ́ ìlà mẹ́ta péré: rain x2 / oṣù yìí — ‘wait’ — daughter: asthma + mould.
Ohun méjì ni ó ń pa àmì níbẹ̀. ‘Lẹ́ẹ̀mejì lóṣù yìí’ gbọ́dọ̀ jáde bí “twice this month”, kì í ṣe “a few times recently”. Àti ‘ọmọ mi obìnrin’: ‘ó’ Yorùbá kò sọ akọ tàbí abo, ṣùgbọ́n Gẹ̀ẹ́sì ń béèrè rẹ̀ ní gbogbo gbólóhùn. Ẹ kọ F tàbí M sí ẹ̀gbẹ́ orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àkọsílẹ̀ yín ní ìbẹ̀rẹ̀ dialogue náà, kí ẹ má baà dúró ní àárín segment kan láti wádìí rẹ̀.
Àwọn ibi mẹ́fà tí ó yẹ kí ẹ ṣọ́ra fún láàrín Yorùbá àti Gẹ̀ẹ́sì
Ìmọ̀ ni ìwọ̀nyí, ẹ sì lè kọ́ wọn. Ohun tí ó wọ́pọ̀ nínú gbogbo wọn ni pé wọ́n ń béèrè ìpinnu lọ́wọ́ yín ní kíákíá. Ẹ ṣe ìpinnu náà ṣáájú ọjọ́ ìdánwò, kí ẹ má baà ṣe é ní àárín segment kan.
- Ìpele ọ̀wọ̀: ẹ/yín àti o/rẹ. ‘You’ Gẹ̀ẹ́sì kò sọ ìpele fún yín; yàrá náà ni ẹ ti ń kà á. Dókítà sí àgbàlagbà, ará ìlú sí òṣìṣẹ́ Centrelink: ‘ẹ/yín’. Òbí sí ọmọ rẹ̀, ọ̀rẹ́ sí ọ̀rẹ́: ‘o/rẹ’. Dialogue Yorùbá ti NAATI fúnra rẹ̀ ń lo ọ̀rọ̀ ọ̀wọ̀: ‘Ẹ káàsán Arábìnrin Black’, ‘Inú mi dùn láti mọ̀ yín’. Ẹ yan ìpele kan fún ẹni kọ̀ọ̀kan ní ìbẹ̀rẹ̀, kí ẹ sì dúró lé e títí dópin. NAATI ní kí ẹ bá ìpele ọ̀wọ̀ olùsọ̀rọ̀ mu; ìpele tí kò bá a mu ń gba àmì lábẹ́ quality of language (dídára èdè).
- ‘Wọ́n’ tí ó dúró fún ẹnì kan. Nígbà tí ẹ bá ń padà sí Gẹ̀ẹ́sì, ‘wọ́n ní kí n padà wá’ tí ó tọ́ka sí dókítà kan ṣoṣo gbọ́dọ̀ di “he told me to come back” tàbí “she told me”. Bí ‘they’ bá jáde, ẹ ti fi ènìyàn kún ìtàn náà.
- Nọ́mbà. Ètò ìṣirò Yorùbá dá lórí ogún, ó sì ń yọ kúrò nínú rẹ̀: ẹ̀ẹ́dógún (15), ẹẹ́rìndínlógún (16), ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25). Ìwọ̀n náà ni ó gbọ́dọ̀ dúró. Bí ‘ẹgbẹ̀rún’ bá bọ́ sínú iye owó kan, iye náà ti di òmíràn pátápátá. Ẹ kọ díjítì sílẹ̀, ẹ sì sọ ọ́ ní kíkún: ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta dọ́là.
- Gígùn Yorùbá. Ọ̀rọ̀ kan Gẹ̀ẹ́sì lè di gbólóhùn ní Yorùbá: interview → ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò, appointment → àdéhùn ìpàdé, eligibility → yíyẹ fún. Segment tí ó tó ọ̀rọ̀ 35 ní Gẹ̀ẹ́sì lè gùn síwájú sí i ní Yorùbá, ìdádúró sì ń tẹ̀lé gígùn. Ẹ mú àwọn gbólóhùn kúkúrú tí ó ti mọ́ ẹnu yín dì mú.
- Ẹ̀ka-èdè. Yorùbá àjùmọ̀lò ni kí ẹ dáhùn ní, bí ó ti wù kí Ìjẹ̀bú, Ẹ̀gbá, Èkìtì, Ìjẹ̀ṣà tàbí Oǹdó ilé yín rí. Kò sí ìpín ẹ̀ka-èdè nínú ìdánwò náà, accent yín kò sì sí nínú àmì.
- Ìdàpọ̀ èdè. Ọ̀rọ̀ àyálò tí ó ti di Yorùbá kò lè pa àmì: fisa, dọ́là, kọ̀ǹpútà, fọ́ọ̀mù. NAATI fúnra rẹ̀ lo ‘Dọ́la’ àti ‘kọ̀ǹpútà’ nínú àwọn dialogue Yorùbá rẹ̀. Ṣùgbọ́n gbólóhùn Gẹ̀ẹ́sì kíkún tí ẹ fi sílẹ̀ láìtúmọ̀ lè kà bí ìtumọ̀ tí kò kọjá.
Àpẹẹrẹ ìṣúná Yorùbá ti NAATI fúnra rẹ̀ kọ 600,000 dọ́là bí ‘Igba mẹ́ta Dọ́la’, ó sì kọ 70,000 bí ‘Àádọ́rin Dọ́là’. Àwọn méjèèjì ti pa ‘ẹgbẹ̀rún’ rẹ́. Ẹ má ṣe tẹ̀lé wọn. Bí ìṣirò ogún-ogún bá ń fà yín sẹ́yìn nígbà ìdánrawò, ẹ yan ọ̀nà kan ṣoṣo fún dialogue kan pátá, kí ẹ sì dúró lé e; ibi tí ẹ bá ti yí ọ̀nà padà ní àárín ni díjítì ti ń sọnù.
Ohun tí ẹ ó ṣe bí ọ̀rọ̀ bá bọ́ lọ́wọ́ yín
Ohun tí ó máa ń ṣẹlẹ̀ ni pé segment kan gùn ju bí ẹ ṣe retí lọ, ohun kan sì fọ́ nínú ìrántí yín ní àárín rẹ̀. Ohun tí ẹ ó ṣe ní ìṣẹ́jú náà ni ó ń pinnu iye àmì tí ẹ ó pàdánù. Hesitation (ìdádúró gígùn) àti àtúnṣe ọ̀rọ̀ ẹni ń gba àmì lábẹ́ quality of delivery (bí ẹ ṣe ń sọ ọ́ jáde).
- Ẹ máa lọ dé òpin segment náà. Bí ọ̀rọ̀ kan bá sọ nù, ẹ fi ààyè sílẹ̀ fún un, ẹ sì tẹ̀síwájú sí èyí tí ó tẹ̀lé e. Ìbẹ̀rẹ̀ tuntun ń jẹ àkókò, ó sì ń fi ìdádúró kún un.
- Ẹ má ṣe tún gbólóhùn kan sọ ní ẹ̀ẹ̀mejì. Àtúnsọ dà bí ìdádúró ní etí olùṣàyẹ̀wò, kò sì ń mú àmì tí ó ti lọ padà.
- Ẹ má ṣe fi àlàyé kún un. ‘Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé...’ tí kò sí lẹ́nu olùsọ̀rọ̀ jẹ́ àfikún, ó sì ń gba àmì lábẹ́ accuracy (ìpéye).
- Bí ọ̀rọ̀ kan bá bọ́ lọ́wọ́ yín, ẹ gbé èrò gbogbo gbólóhùn náà lọ. Ọ̀rọ̀ kan tí ó sọnù kéré sí gbólóhùn kíkún tí ó sọnù.
- Ẹ sọ ọ́ ní ìwọ̀n kan, ní ìdákẹ́ jẹ́ẹ́. Ìyára tí ó pọ̀ jù ń mú kí ọ̀rọ̀ dàrú, ìyẹn sì ń dà bí ìtumọ̀ tí ó yí padà.
NAATI sọ pé segment kan ṣoṣo nínú dialogue kọ̀ọ̀kan ni ẹ lè tún gbọ́ (repeat) láìsí ìyọkúrò àmì; àtúngbọ́ kejì ń gba àmì lábẹ́ accuracy. Ẹ pa àǹfààní kan ṣoṣo yẹn mọ́ fún nọ́mbà tàbí orúkọ tí ó bọ́ lọ́wọ́ yín, kí ẹ sì máa ṣe ìdánrawò bí ẹni pé segment kọ̀ọ̀kan yóò kọjá ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo. Bí àtúngbọ́ náà ṣe ń lọ wà nínú CCL Test Candidate Instructions ti NAATI.
Ọ̀nà kan wà láti fẹ ìrántí yín sí i, kò sì ní ohun èlò kankan nínú. Ẹ gbọ́ segment kan, ẹ pa ẹ̀rọ náà, kí ẹ sì sọ ọ́ padà ní èdè kan náà, láìsí àkọsílẹ̀. Nígbà tí ìyẹn bá ti rọrùn, ẹ fi àkọsílẹ̀ kún un, lẹ́yìn náà kí ẹ yí èdè padà. Ìròyìn rédíò tàbí ìròyìn BBC Yorùbá ìṣẹ́jú mẹ́ta dára fún un: ohùn tí ẹ kò mọ̀, ọ̀rọ̀ tí ẹ kò retí.
Ètò ìdánrawò ọ̀sẹ̀ mẹ́rin sí mẹ́fà
Ètò tí ó ṣeé ṣe fún ẹni tí ó ń ṣiṣẹ́ ní kíkún: ìṣẹ́jú ogójì ní ọjọ́ mẹ́rin nínú ọ̀sẹ̀. Ìtẹ̀lé ni ó ṣe pàtàkì jù, ju iye wákàtí lọ.
- Ọ̀sẹ̀ 1: ìwọ̀n ìbẹ̀rẹ̀. Ẹ ṣe dialogue Yorùbá ọ̀fẹ́ kan ti NAATI láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, pẹ̀lú ẹ̀rọ ìgbàsílẹ̀ ohùn. Lẹ́yìn náà, ẹ tẹ́tí sí i pẹ̀lú PDF náà ní ọwọ́ yín, kí ẹ sì kọ gbogbo ohun tí ó bọ́ sílẹ̀. Ìwé iṣẹ́ yín nìyẹn.
- Ọ̀sẹ̀ 2: gbólóhùn tí ó ń pẹ́ dé. Ẹ mú àwọn kókó ọ̀rọ̀ mẹ́ta tí ó wúwo jù lórí yín (ìlera, Centrelink, ilé), kí ẹ sì kọ gbólóhùn Yorùbá kúkúrú fún àwọn èrò tí ó ń pẹ́ dé lẹ́nu yín. Ẹ sọ wọ́n ní ohùn rara títí wọn ó fi yára.
- Ọ̀sẹ̀ 3: segment kọ̀ọ̀kan, ẹ̀gbẹ́ méjèèjì. Segment kan, àkọsílẹ̀ kan, ìtumọ̀ kan, láìsí ìdúró. Ẹ ṣe ìdajì rẹ̀ ní Gẹ̀ẹ́sì → Yorùbá, ìdajì ní Yorùbá → Gẹ̀ẹ́sì. Ẹ̀gbẹ́ Gẹ̀ẹ́sì → Yorùbá ni ó gbọ́dọ̀ gba àkókò púpọ̀ jù.
- Ọ̀sẹ̀ 4: dialogue kíkún. Dialogue méjì lẹ́ẹ̀kan náà, láìsí ìdáwọ́dúró, bí ọjọ́ ìdánwò gan-an. Àárẹ̀ tí ó ń dé nínú dialogue kejì ni ìdí tí ìlà 29/45 fi ń kó àwọn ènìyàn.
- Ọ̀sẹ̀ 5 sí 6, bí ẹ bá ní wọn: àtúnṣe. Ẹ padà sí àwọn segment tí ẹ ti pàdánù àmì nínú wọn nìkan. Ẹ tún wọn ṣe títí wọn ó fi kọjá ní ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lẹ́ẹ̀mẹta.
Ohun kan ni ẹ ó pàdé níbẹ̀. Dialogue ọ̀fẹ́ mẹ́rin péré ni NAATI tẹ̀ jáde ní Yorùbá: Education, Employment, Financial àti Social Services. Lẹ́yìn ọ̀sẹ̀ méjì, ẹ ó ti mọ ìdáhùn wọn sórí, ìdánrawò náà kò sì ní jẹ́ ìdánrawò mọ́. Dialogue tuntun ni ohun tí ó kù.
Ẹ fi àkọsílẹ̀ yín ṣe dialogue tuntun kan. Mock test kan àti ìdánrawò kan wà lọ́fẹ̀ẹ́, pẹ̀lú àmì àti àlàyé fún segment kọ̀ọ̀kan.
Ṣe mock test ọ̀fẹ́ kanBí a ṣe ń lo àwọn fídíò ìdánrawò ọ̀fẹ́ lórí YouTube
Àwọn dialogue Yorùbá tí ó wà lórí ìkànnì YouTube wa ń ṣiṣẹ́ bí ẹ bá lò wọ́n bí ìdánwò. Dialogue kan ni ó ń lọ láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin, ìkàsílẹ̀ àkókò sì ń tẹ̀lé segment kọ̀ọ̀kan: ẹ sọ ìtumọ̀ yín sókè nígbà náà gan-an, ẹ kò sì ní dúró de ìdáhùn tí ó tọ́.
- Ẹ fi fóònù kan gba ohùn yín sílẹ̀ nígbà tí ẹ ń wo fídíò náà lórí ẹ̀rọ mìíràn.
- Ẹ ṣe àkọsílẹ̀ lórí bébà ní àkókò kan náà. Note-taking tí a kò ṣe ìdánrawò rẹ̀ kì í ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìdánwò.
- Lẹ́yìn náà ni ẹ ó tẹ́tí sí ohùn ara yín, pẹ̀lú ìwé kan: ohun tí ó bọ́, ohun tí ẹ fi kún un, àti ibi tí ẹ dúró sí.
- Ẹ má ṣe dá fídíò náà dúró láti kọ̀wé. Bí ọwọ́ yín bá mọ́ dídá a dúró nígbà ìdánrawò, ó máa dúró ní ọjọ́ ìdánwò, níbi tí kò ti sí ìdádúró kankan.
Àwọn fídíò ìdánrawò ní èdè Yorùbá
Àwọn fídíò ìdánrawò tuntun
Ọ̀wọ́ fídíò ìgbáradì ní Gẹ̀ẹ́sì (note-taking, àkójọ ọ̀rọ̀, ìlànà ìdánwò) wà lórí ìkànnì kan náà.
Ìgbáradì ọjọ́ ìdánwò (yàrá àti ẹ̀rọ)
Lórí ayélujára nìkan ni wọ́n ń ṣe ìdánwò náà, láti ilé yín, pẹ̀lú olùṣọ́ (proctor) tí ń wò yín. Àtòjọ ohun èlò tí NAATI ń béèrè wà lórí ojú-ìwé ìtọ́sọ́nà wa; ẹ dán gbogbo rẹ̀ wò ní ọ̀sẹ̀ kan ṣáájú, kì í ṣe ní òwúrọ̀ ọjọ́ náà.
Yàrá náà ni ìdajì iṣẹ́ náà. Ẹ ti ẹnu ọ̀nà, ẹ sọ fún àwọn ará ilé pé kí wọ́n má ṣe wọlé, ẹ pa ìkìlọ̀ fóònù rẹ́, ẹ sì fi omi kan sí orí tábìlì. Ariwo ilé kì í pa àmì fúnra rẹ̀; ohun tí ó ń pa àmì ni pé ẹ ó dúró láti wádìí bóyá ohun tí ẹ gbọ́ ni ó sọ.
Ìṣẹ́jú àkọ́kọ́ ni ó máa ń pọn dandan jù. Ẹ ṣe ìdánrawò gbẹ̀yìn yín ní àkókò kan náà ti ọjọ́ tí ìdánwò yín yóò wáyé. Ohùn àárọ̀ àti ohùn alẹ́ yàtọ̀ sí ara wọn. Ẹ sì sọ ọ̀rọ̀ díẹ̀ ní Yorùbá rara ṣáájú kí ẹ tó wọlé, kí ẹnu má baà kọ́kọ́ ṣí sí Yorùbá lórí segment àkọ́kọ́ ti ìdánwò náà.